Orin Solomoni7yor_bib

1Báwo ni ẹsẹ̀ rẹ ti ní ẹwà tó nínú bàtà.Ìwọ ọmọbìnrin ọba!Oríkèé itan rẹ rí bí ohun ọ̀ṣọ́iṣẹ́ ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà2Ìdodo rẹ rí bí àwotí kì í ṣe aláìní ọtí,ìbàdí rẹ bí òkìtì alikamatí a fi lílì yíká.3Ọmú rẹ rí bí abo egbin méjìtí wọ́n jẹ́ ìbejì àgbọ̀nrín.4Ọrùn rẹ rí bí ilé ìṣọ́ eyín erin.Ojú rẹ rí bí adágún ní Heṣboniní ẹ̀bá ẹnu ibodè Bati-Rabbimu.Imú rẹ rí bí ilé ìṣọ́ Lebanonití ó kọ ojú sí Damasku.5Bí òkè Karmeli ṣe ṣe adé yí àwọn òkè ká,bẹ́ẹ̀ ni irun orí rẹ ṣe adé yí orí rẹ káa fi àìdi irun rẹ mú ọba ní ìgbèkùn.6Báwo ni ẹwà rẹ ti pọ̀ tóbáwo ni o sì ti dára tó ìwọ olùfẹ́ mi nínú ìfẹ́?7Ìdúró rẹ rí bí igi ọ̀pẹ,àti ọmú rẹ bí ìdì èso àjàrà.8Mo ní, “Èmi yóò gun igi ọ̀pẹ lọ,èmi yóò di ẹ̀ka rẹ̀ mú.”Kí ọmú rẹ rí bí ìdì èso àjàrà,àti èémí imú rẹ bí i ápù.9Àti ìfẹnukonu rẹ rí bí ọtí wáìnì tí ó dára jùlọ.Olólùfẹ́Tí ó kúnná tí ó sì dùn,tí ń mú kí ètè àwọn tí ó sùn kí ó sọ̀rọ̀.10Ti olùfẹ́ mi ni èmi í ṣe,èmi sì ni ẹni tí ó wù ú.11Wá, olùfẹ́ mi, jẹ́ kí a lọ sí ibi pápá,jẹ́ kí a lo àṣálẹ́ ní àwọn ìletò.12Jẹ́ kí a lọ sínú ọgbà àjàrà ní kùtùkùtùláti wo bí àjàrà rúwébí ìtànná àjàrà bá là.Àti bí pomegiranate bá ti rudi,níbẹ̀ ni èmi yóò ti fi ìfẹ́ mi fún ọ.13Àwọn èso mándrákì mú òórùn wọn jádení ẹnu-ọ̀nà wa ni onírúurú àṣàyàn èso,èso tuntun àti ọjọ́ pípẹ́tí mo ti kó pamọ́ fún ọ, olùfẹ́ mi.