Orin Solomoni6yor_bib
1Níbo ni olùfẹ́ rẹ lọ,ìwọ arẹwà jùlọ láàrín àwọn obìnrin?Níbo ni olùfẹ́ rẹ yà sí,kí a lè bá ọ wá a?2Olùfẹ́ mi ti sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọgbà rẹ̀,sí ibi ibùsùn tùràrí,láti máa jẹ nínú ọgbàláti kó ìtànná lílì jọ.3Èmi ni ti olùfẹ́ mi, olùfẹ́ mi sì ni tèmi,Ó ń jẹ láàrín ìtànná lílì.4Ìwọ lẹ́wà olùfẹ́ mi, bí i Tirsa,ìwọ lẹ́wà bí i Jerusalẹmu,ìwọ ògo bí ogun pẹ̀lú ọ̀págun.5Yí ojú rẹ kúrò lára mi;nítorí ojú rẹ borí mi.Irun rẹ rí bí i ọ̀wọ́ ewúrẹ́tí ó sọ̀kalẹ̀ wá láti Gileadi.6Eyín rẹ rí bí ọ̀wọ́ àgùntàn,tí ó gòkè láti ibi ìwẹ̀ rẹ̀ wá,gbogbo wọn bí ìbejì,kò sì ṣí ọ̀kankan tí ó yàgàn nínú wọn.7Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́bàá ìbòjú rẹ,rí bí ẹ̀là èso pomegiranate.8Ọgọ́ta ayaba ní ń bẹ níbẹ̀,àti ọgọ́rin àlè,àti àwọn wúńdíá láìníye.9Àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi, ọ̀kan ni,ọ̀kan ṣoṣo ọmọbìnrin ìyá rẹ̀,ààyò ẹyọ kan ṣoṣo ẹni tí ó bí i.Àwọn obìnrin rí i wọ́n pè é ní alábùkún fúnàwọn ayaba àti àwọn àlè gbé oríyìn fún un.10Ta ni èyí tí ó tàn jáde bí i ìràwọ̀ òwúrọ̀,tí ó dára bí òṣùpá, tí ó mọ́lẹ̀ bí oòrùn,tí ó ní ẹ̀rù bí i jagunjagun pẹ̀lú ọ̀págun?11Èmi sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibi ọgbà èso igiláti wo àwọn ẹ̀ka igi tuntun ní àfonífojì,láti rí i bí àjàrà rúwé,tàbí bí pomegiranate ti rudi.12Kí èmi tó mọ̀,àárẹ̀ ọkàn mú mi, mo sì fẹ́ kí ń wà láàrín àwọn ènìyàn mi.13Padà wá, padà wá, ìwọ ọmọ Ṣulamati;padà wá, padà wá, kí àwa kí ó lè yọ́ ọ wò.Olùfẹ́Èéṣe tí ẹ̀yin fẹ́ yọ́ Ṣulamati wò,bí ẹni pé orin ijó Mahanaimu?