Orin Solomoni5yor_bib

1Mo ti dé inú ọgbà mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi;mo ti kó òjìá pẹ̀lú òórùn dídùn mi jọ.Mo ti jẹ afárá mi pẹ̀lú oyin mi;mo ti mu ọtí wáìnì mi pẹ̀lú wàrà mi.Ọ̀rẹ́Ẹ jẹ, ẹ̀yin ọ̀rẹ́, ẹ mu,àní ẹ mu àmuyó, ẹ̀yin olùfẹ́.2Mo ti sùn ṣùgbọ́n ọkàn mi jí.Gbọ́! Olólùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn.“Ṣí i fún mi, arábìnrin mi, olùfẹ́ mi,àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi,orí mi kún fún omi ìrì,irun mi kún fún òtútù òru.”3Mo ti bọ́ aṣọ ìgúnwà miṣé èmi gbọdọ̀ tún gbé e wọ̀?Mo ti wẹ ẹsẹ̀ miṣé èmi gbọdọ̀ tún tì í bọ eruku?4Olùfẹ́ mi na ọwọ́ rẹ̀ láti inú ihò ìlẹ̀kùninú mi sì yọ́ sí i.5Èmi dìde láti ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,òjìá bẹ̀rẹ̀ sí í kán ní ọwọ́ mi,òjìá olóòórùn ń ti ara ìka mi ń sànsí orí ìdìmú ìlẹ̀kùn.6Èmi ṣí ìlẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,ṣùgbọ́n olùfẹ́ mi ti kúrò, ó ti lọọkàn mi gbọgbẹ́ fún lílọ rẹ̀.Mo wá a kiri ṣùgbọ́n, n kò rí i.Mo pè é ṣùgbọ́n, kò dáhùn.7Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ ìlú rí mibí wọ́n ti ṣe ń rìn yí ìlú ká.Wọ́n nà mí, wọ́n sá mi lọ́gbẹ́;wọ́n gba ìborùn mi lọ́wọ́ mi.Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ odi!8Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, mo bẹ̀ yínbí ẹ̀yin bá rí olùfẹ́ mi,kí ni ẹ̀yin yóò wí fún un?Ẹ wí fún un pé àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mi.9Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tókù lọ,ìwọ arẹwà jùlọ láàrín àwọn obìnrin?Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tókù lọtí ìwọ fi ń fi wá bú bẹ́ẹ̀?10Olùfẹ́ mi ní ìtànṣán ó sì pọ́nó ní ọlá ju ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) lọ.11Orí rẹ̀ rí bí i wúrà tí ó dára jùlọìdì irun rẹ̀ rí bí i imọ̀ ọ̀pẹó sì dúdú bí i ẹyẹ ìwò.12Ojú rẹ̀ rí bí i ti àdàbàní ẹ̀bá odò tí ń sàn,tí a fi wàrà wẹ̀,tí ó jì, tí ó sì dákẹ́ rọ́rọ́.13Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ rí bí ibùsùn tùràrítí ó sun òórùn tùràrí dídùnÈtè rẹ̀ rí bí i ìtànná lílìó ń kán òjìá olóòórùn dídùn.14Apá rẹ̀ rí bí i ọ̀pá wúrà,tí a to ohun ọ̀ṣọ́ sí yíká.Ara rẹ̀ rí bí i eyín erin dídántí a fi safire ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.15Ẹsẹ̀ rẹ̀ rí bí i òpó mabutí a gbé ka ihò ìtẹ̀bọ̀ wúrà dáradára.Ìrísí rẹ̀ rí bí igi kedari Lebanoni,tí dídára rẹ̀ kò ní ẹgbẹ́.16Ẹnu rẹ̀ jẹ́ adùn fún ara rẹ̀ó wu ni pátápátá.Háà! Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu.Èyí ni olùfẹ́ mi, èyí sì ni ọ̀rẹ́ mi.