Orin Solomoni3yor_bib
1Ní orí ibùsùn mi ní òrumo wá ẹni tí ọkàn mí fẹ́;mo wá a, ṣùgbọ́n èmi kò rí i.2Èmi yóò dìde nísinsin yìí, èmi yóò sì rìn lọ káàkiri ìlú,ní àwọn òpópónà àti ní àwọn gbangba òde;èmi yóò wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́.Bẹ́ẹ̀ ni mo wá a ṣùgbọ́n èmi kò rí i.3Àwọn ọdẹ tí ń ṣọ́ ìlú rí mibí wọ́n ṣe ń rìn yíká ìlú.“Ǹjẹ́ ìwọ ti rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?”4Gẹ́rẹ́ tí mo fi wọ́n sílẹ̀ni mo rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́.Mo dìímú, èmi kò sì jẹ́ kí ó lọtítí tí mo fi mú u wá sílé ìyá mi,sínú yàrá ẹni tí ó lóyún mi.5Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu,mo fi àwọn abo egbin àti abo àgbọ̀nrín igbó fi yín búkí ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókèkí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú.6Ta ni ẹni tí ń ti ijù jáde wábí ọ̀wọ̀n èéfíntí a ti fi òjìá àti tùràrí kùn lárapẹ̀lú gbogbo ìpara olóòórùn oníṣòwò?7Wò ó! Àkéte rẹ̀ tí í ṣe ti Solomoni,àwọn akọni ọgọ́ta ni ó wà yí i ká,àwọn akọni Israẹli,8gbogbo wọn ni ó mú idà lọ́wọ́,gbogbo wọn ní ìmọ̀ nínú ogun,idà oníkálùkù wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀,wọ́n múra sílẹ̀ fún ìdágìrì òru9Solomoni ọba ṣe àkéte fún ara rẹ̀;o fi igi Lebanoni ṣe é.10Ó fi fàdákà ṣe òpó rẹ̀,o fi wúrà ṣe ibi ẹ̀yìn rẹ̀.Ó fi elése àlùkò ṣe ibùjókòó rẹ̀,inú rẹ̀ ni ó ko àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọ̀nyí sí.“Pẹ̀lú ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Jerusalẹmu.”11Ẹ jáde wá, ẹ̀yin ọmọbìnrin Sioni,kí ẹ sì wo ọba Solomoni tí ó dé adé,adé tí ìyá rẹ̀ fi dé ení ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀,ní ọjọ́ ayọ̀ ọkàn rẹ̀.