Saamu99yor_bib

1Olúwa jẹ ọba;jẹ́ kí ayé kí ó wárìrìÓ jókòó lórí ìtẹ́ kérúbùjẹ́ kí ayé kí ó wárìrì.2Olúwa tóbi ní Sioni;Ó sì ga jù gbogbo orílẹ̀-èdè lọ.3Kí wọ́n sì yin orúkọ rẹ̀ tí ó tóbití ó ni ẹ̀rù, Mímọ́ ni Òun.
4Ọba náà ní agbára, ó sì fẹ́ òdodo,ìwọ fi ìdí àìṣègbè múlẹ̀;ìwọ ṣe ohun tí ó tọ́ àti ohun tí ó yẹ nínú Jakọbu.5Gbígbéga ni Olúwa Ọlọ́run waẹ foríbalẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀; ó jẹ́ mímọ́.
6Mose àti Aaroni wà nínú àwọn àlùfáà rẹ̀Samuẹli wà nínú àwọn tí ó ń ké pe orúkọ rẹ̀wọ́n ké pe Olúwa, ó sì dá wọn lóhùn.7Ó sọ̀rọ̀ sí wọn nínú ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀,wọ́n pa ẹ̀rí rẹ̀ mọ́ àti ìlànà tí ó fún wọn.
8Olúwa Ọlọ́run wa, ó dá wọn lóhùn;ó jẹ́ Ọlọ́run tí ó ń dáríjì àwọn ọmọ Israẹliìwọ tí ó ń fi ìyà àìṣedéédéé wọn jẹ wọ́n.9Gbígbéga ni Olúwa Ọlọ́run wakí a sìn ín ní òkè mímọ́ rẹ̀nítorí Olúwa Ọlọ́run wa jẹ́ mímọ́.