Saamu98yor_bib
1Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa,nítorí tí ó ṣe ohun ìyanu;ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti apá mímọ́ rẹ̀o ṣe iṣẹ́ ìgbàlà fún un2Olúwa ti sọ ìgbàlà rẹ̀ di mí mọ̀o fi òdodo rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè.3Ó rántí ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ fún àwọn ará ilé Israẹli;gbogbo òpin ayé ni ó ti ríiṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run wa.4Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé,ẹ bú sáyọ̀, ẹ kọrin ìyìn,5ẹ fi dùùrù kọrin sí Olúwa, pẹ̀lú dùùrù àti ìró ohùn orin mímọ́,6pẹ̀lú ìpè àti fèrèẹ hó fún ayọ̀ níwájú Olúwa ọba.7Jẹ́ kí òkun kí ó hó pẹ̀lú gbogboohun tí ó wà nínú rẹ̀,Gbogbo ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.8Ẹ jẹ́ kí odo kí ó ṣápẹ́,ẹ jẹ́ kí òkè kí ó kọrin pẹ̀lú ayọ̀;9ẹ jẹ́ kí wọn kọrin níwájú Olúwa,nítorí tí yóò wá ṣèdájọ́ ayébẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè nínú òdodoàti àwọn ènìyàn ní àìṣègbè pẹ̀lú.