Saamu97yor_bib
1Olúwa jẹ ọba, jẹ́ kí ayé kí ó yọ̀jẹ́ kí inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù kí ó dùn.2Ojú ọ̀run àti òkùnkùn yíkáòdodo àti ìdájọ́ ni ó ṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀.3Iná ń jó níwájú rẹ̀. Ó sì ń jó àwọn ọ̀tá rẹ̀ yíkákiri.4Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn ó sì kárí ayéayé rí i ó sì wárìrì.5Òkè gíga yọ́ gẹ́gẹ́ bí ìda níwájú Olúwa,níwájú Olúwa gbogbo ayé.6Àwọn ọ̀run ròyìn òdodo rẹ̀, gbogbo ènìyàn sì rí ògo rẹ̀.7Gbogbo àwọn tí ń sin ère fínfín ni ojú yóò tì,àwọn tí ń fi ère gbéraga,ẹ máa sìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́run!8Sioni gbọ́, inú rẹ̀ sì dùninú àwọn ilé Juda sì dùn,nítorí ìdájọ́ rẹ, Olúwa.9Nítorí pé ìwọ, Olúwa, ni ó ga ju gbogbo ayé lọìwọ ni ó ga ju gbogbo òrìṣà lọ.10Jẹ kí gbogbo àwọn tí ó fẹ́Olúwa, kórìíra ibi, ó pa ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́ó gbà wọ́n ní ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú.11Ìmọ́lẹ̀ tàn sórí àwọn olódodoàti ayọ̀ nínú àlàyé ọkàn.12Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olódodo,kí ẹ sì yin orúkọ rẹ̀ mímọ́.