Saamu96yor_bib

1Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa,ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé.2Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ rẹ̀ẹ sọ ti ìgbàlà rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́.3Ẹ sọ ti ògo rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdèàti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrín gbogbo ènìyàn.
4Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ́ sí;òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìṣà lọ.5Nítorí asán ni gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdèṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run.6Ọlá àti ọláńlá wà ní iwájú rẹ̀agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ rẹ̀.
7Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìbátan ènìyàn,ẹ fi agbára àti ògo fún Olúwa.8Ẹ fi ògo tí ó tọ́ sí Olúwa fún un;ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá rẹ̀.9Ẹ máa sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́ rẹ̀;ẹ wárìrì níwájú rẹ̀ gbogbo ayé.10Sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, “Olúwa jẹ ọba.”A fi ìdí ayé múlẹ̀, tí kò sì lè yí;ẹni tí yóò fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ ènìyàn.
11Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, kí ayé sì pariwojẹ́ kí pápá òkun kí ó hó pẹ̀lú ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀.12Jẹ́ kí oko kún fún ayọ̀, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀;nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóò máa yọ̀.13Wọn yóò kọrin níwájú Olúwa,nítorí tí ó ń bọ̀ wá, ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé.Yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayéàti ti àwọn ènìyàn ni yóò fi òtítọ́ rẹ̀ ṣe.