Saamu95yor_bib

1Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a kọ orin ayọ̀ sí Olúwa,ẹ jẹ́ kí a kígbe sókè sí àpáta ìgbàlà wa.2Ẹ jẹ́ kí a wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́kí a sì pòkìkí rẹ̀ pẹ̀lú ohun èlòorin àti ìyìn.
3Nítorí Olúwa Ọlọ́run títóbi ni,ọba tí ó tóbi ju gbogbo òrìṣà lọ.4Ní ọwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà,ṣóńṣó orí òkè tirẹ̀ ní ṣe.5Tirẹ̀ ni Òkun, nítorí òun ni ó dá aàti ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.
6Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a foríbalẹ̀ kí a sìn ín,ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀ níwájúOlúwa ẹni tí ó dá wa,7nítorí òun ni Ọlọ́run wa,àwa sì ni ènìyàn pápá rẹ̀,àti ọ̀wọ́ ẹran ni abẹ́ ìpamọ́ rẹ̀.Lónìí tí ìwọ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,8“Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ní Meriba,àti bí ẹ ti ṣe ní ọjọ́ náà ní Massa ní aginjù,9nígbà tí àwọn baba yín dán mi wòtí wọn wádìí mi,tí wọn sì rí iṣẹ́ mi.10Fún ogójì ọdún ni èmi fi bínú sí ìran náà;mo wí pé, ‘Wọ́n jẹ́ ènìyàn tí ọkàn wọn ṣáko lọwọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’11Nítorí náà ni mo kéde ìbúra nínú ìbínú mi,‘Wọn kì yóò wọ ibi ìsinmi mi.’ ”