Saamu93yor_bib

1Olúwa ń jẹ ọba, ọláńlá ni ó wọ̀ ní aṣọ;ọláńlá ni Olúwa wọ̀ ní aṣọàti ìhámọ́ra rẹ̀ pẹ̀lú agbára.Ó fi ìdí ayé múlẹ̀;kò sì le è yí.2Ìjọba rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́;ìwọ wà títí ayérayé.
3A ti gbé òkun sókè, Olúwa,òkun ti gbé ohùn wọn sókè;òkun ti gbé rírú omi wọn sókè.4Ó ni ògo ju àrá omi ńlá lọ,ó ni ògo ju òkun rírú lọOlúwa ga ní ògo.
5Ẹ̀rí rẹ̀ dúró ṣinṣin;ìwà mímọ́ ni ó fi ṣe ilé rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́fún ọjọ́ àìlópin, Olúwa.