Saamu9yor_bib
Fún adarí orin. Ní ti ohun orin. “Ní ti ikú ọmọ.” Saamu ti Dafidi.
1Èmi ó yìn ọ́, Olúwa, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;èmi ó sọ ti ìyanu rẹ gbogbo.2Inú mi yóò dùn, èmi yóò sì yọ̀ nínú rẹ;èmi ó kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ, Ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ.3Àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà;wọ́n kọsẹ̀ wọn sì ṣègbé níwájú rẹ.4Nítorí ìwọ ti di òtítọ́ àti ọ̀ràn mi mú;ìwọ ti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ, láti ṣe ìdájọ́ òdodo.5Ìwọ ti bá orílẹ̀-èdè wí, Ìwọ sì ti pa ẹni búburú run;Ìwọ ti yọ orúkọ wọn kúrò láé àti láéláé.6Ìparun àìlópin ti borí àwọn ọ̀tá,ìwọ ti fa àwọn ìlú wọn tu;àní ìrántí wọn sì ti ṣègbé.7Olúwa jẹ ọba títí láé;ó ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ fún ìdájọ́.8Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ ayé ní òdodo;yóò ṣe àkóso ènìyàn pẹ̀lú òdodo.9Olúwa ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú.10Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀lé ọ,nítorí, Olúwa, kò kọ àwọn tó ń wá a sílẹ̀.11Kọ orin ìyìn sí Olúwa, tí o ń jẹ ọba ní Sioni;kéde láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun tí ó ṣe.12Nítorí ẹni tí ó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ rántí;òun kò kọ ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.13Olúwa, wo bí àwọn ọ̀tá ṣe ń ṣe inúnibíni sí mi!Ṣàánú, kí o sì gbé mí sókè kúrò ní ẹnu-ọ̀nà ikú,14kí èmi kí ó lè sọ ti ìyìn rẹni ẹnu-ọ̀nà àwọn ọmọbìnrin Sioniàti láti máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.15Àwọn orílẹ̀-èdè ti jì sí kòtò tí wọn ti gbẹ́;ẹsẹ̀ wọn ni àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ kọ́.16A mọ Olúwa nípa òdodo rẹ̀;àwọn ènìyàn búburú ni a dẹ́kun mú nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn.17Àwọn ènìyàn búburú ni a ó dà sí isà òkú,àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọ́run.18Ṣùgbọ́n àwọn aláìní ni a kò ní gbàgbé láéláé,ìrètí àwọn ti ó tálákà ni a kì yóò gbàgbé láéláé.19Dìde, Olúwa, má ṣe jẹ́ kí ènìyàn borí;jẹ́ kí a ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ni iwájú rẹ.20Lù wọ́n pẹ̀lú ìpayà, Olúwa;jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé ènìyàn lásán ni wọ́n. Sela.