Saamu87yor_bib

Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Orin.

1Ó ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí òkè mímọ́;2Olúwa fẹ́ràn ẹnu-ọ̀nà Sioniju gbogbo ibùgbé Jakọbu lọ.
3Ohun ológo ni a sọ nípa rẹ̀,ìlú Ọlọ́run,4“Èmi ó dárúkọ Rahabu àti Babeliláàrín àwọn tí ó jẹ́wọ́ mi:Filistia pẹ̀lú, àti Tire, pẹ̀lú Kuṣi,yóò sọ pé, ‘Èyí ni a bí ní Sioni.’ ”5Nítòótọ́, ti Sioni ni a ó sọ,“Eléyìí àti eléyìí ni a bí nínú rẹ̀,àti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo ni yóò fìdí rẹ̀ múlẹ̀.”6Olúwa yóò kọ nínú àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀:“Eléyìí ni a bí ní Sioni.”
7Àti àwọn olórin àti àwọn tí ń luohun èlò orin yóò wí pé,“Gbogbo orísun mi ń bẹ nínú rẹ.”