Saamu86yor_bib
Àdúrà ti Dafidi.
1Gbọ́, Olúwa, kí o sì dá mi lóhùn,nítorí mo jẹ́ tálákà àti aláìní.2Dáàbò bò ayé mi, nítorí a ti yà mí sọ́tọ̀ fún ọ:ìwọ ni Ọlọ́run mi,gbà ìránṣẹ́ rẹ làtí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.3Ṣàánú fún mi, Olúwa,nítorí èmi ń pè ọ́ ní gbogbo ọjọ́.4Mú ayọ̀ wà fún ìránṣẹ́ rẹ,nítorí ìwọ, Olúwa,ni mo gbé ọkàn mí sókè sí.5Ìwọ ń dáríjì, ìwọ sì dára, Olúwa,ìwọ sì ṣàánú fún gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́.6Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa;tẹ́tí sí ẹkún mi fún àánú.7Ní ọjọ́ ìpọ́njú mi èmi yóò pè ọ́,nítorí ìwọ yóò dá mi lóhùn.8Nínú àwọn òrìṣà kò sí ẹni tí ó dàbí i rẹ, Olúwa:kò sí àwọn iṣẹ́ tí a lè fiwé tìrẹ.9Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ dáyóò wá láti wá jọ́sìn níwájú rẹ, Olúwa;wọn ó mú ògo wà fún orúkọ rẹ̀.10Nítorí pé ìwọ tóbi, ìwọ sì ń ṣe ohun ìyanu;ìwọ nìkan ni Ọlọ́run.11Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa,èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ rẹ;fún mi ní ọkàn tí kì í yapa,kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ rẹ.12Èmi ó yìn ọ́, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;èmi ó fògo fún orúkọ rẹ títí láé.13Nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ si mi;ìwọ ti gbà mí kúrò nínú ọ̀gbun isà òkú.14Àwọn onígbèéraga ń dojúkọ mí, Ọlọ́run;àti ìjọ àwọn alágbára ń wáọkàn mi kiri,wọn kò sì fi ọ́ pè.15Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere,Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́.16Yípadà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi;fún àwọn ènìyàn rẹ ní agbárakí o sì gba ọ̀dọ́mọkùnrin ìránṣẹ́bìnrin rẹ là.17Fi àmì hàn mí fún rere,kí àwọn tí ó kórìíra mi lè ri,kí ojú lè tì wọ́n, nítorí ìwọ Olúwani ó ti tù mí nínú.