Saamu84yor_bib
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.
1Ibùgbé rẹ̀ ti lẹ́wà tó,Olúwa àwọn ọmọ-ogun!2Ọkàn mi ń ṣàfẹ́rí nítòótọ́ó tilẹ̀ pòǹgbẹ fún àgbàlá Olúwaàyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀sí Ọlọ́run alààyè.3Nítòótọ́ ológoṣẹ́ ri ilé,ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara rẹ̀,níbi tí yóò máa pa ọmọ rẹ̀ mọ́ sí:ibùgbé ní tòsí pẹpẹ rẹ̀,Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi.4Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé rẹ;wọn ó máa yìn ọ́ títí láé.5Ìbùkún ni fún àwọn tí agbára wọn wà nínú rẹàwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò.6Àwọn tí ń la àfonífojì omijé lọwọn sọ ọ́ di kàngaàkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó.7Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipátítí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Sioni.8Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa Ọlọ́run Alágbára;tẹ́tí sí mi, Ọlọ́run Jakọbu.9Wo asà wa, Ọlọ́run;fi ojú àánú wò àwọn ẹni àmì òróró rẹ.10Dídára ní ọjọ́ kan ní ààfin rẹju ẹgbẹ̀rún (1,000) ọjọ́ lọ;èmi o kúkú máa ṣe aṣọ́nà nínú ilé Ọlọ́run mijù láti gbé ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú.11Nítorí Olúwa Ọlọ́run jẹ́ òòrùn àti asà;Olúwa fún ni ní ojúrere àti ọlá;kò sí ohun rere kan tí yóò fàsẹ́yìnfún àwọn tí ó rìn ní àìlábùkù.12Olúwa àwọn ọmọ-ogun,ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.