Saamu83yor_bib
Orin. Saamu ti Asafu.
1Ọlọ́run, má ṣe dákẹ́;má ṣe dákẹ́, Ọlọ́run má ṣe dúró jẹ́ẹ́.2Wo bí àwọn ọ̀tá rẹ ti ń rọ́kẹ̀kẹ̀ lọ,bi àwọn ọ̀tá rẹ ti ń gbé ohùn wọn sókè.3Pẹ̀lú àrékérekè ni wọn dìtẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ;wọn sí dìtẹ̀ mọ́ àwọn tí o fẹ́.4Wọn wí pé, “wá, ẹ jẹ́ kí á pa wọ́n run bí orílẹ̀-èdè,kí orúkọ Israẹli ma bá a sí ní ìrántí mọ́.”5Wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan;wọ́n ṣe àdéhùn láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ6Àgọ́ Edomu àti ti àwọn ará Iṣmaeli,ti Moabu àti ti Hagari7Gebali, Ammoni àti Amaleki,Filistia, pẹ̀lú àwọn ènìyàn Tire.8Asiria pẹ̀lú ti darapọ̀ mọ́ wọnláti ran àwọn ọmọ Lọti lọ́wọ́. Sela.9Ṣe sí wọn bí ìwọ ti ṣe sí Midianibí o ti ṣe sí Sisera àti Jabini ní odò Kiṣoni,10ẹni tí ó ṣègbé ní Endorití wọn sì dàbí ààtàn ní orí ilẹ̀.11Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí Orebu àti Seebu,àwọn ọmọ-aládé wọn bí Seba àti Salmunna,12tí ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a gbà ní ìníàní pápá oko tútù Ọlọ́run.”13Ìwọ Ọlọ́run, ṣe wọ́n bí ààjà,bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́.14Bí iná ti í jó igbó,àti bí ọ̀wọ́-iná ti ń mú òkè ńlá gbiná,15bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ẹ̀fúùfù líle rẹ lépa wọndẹ́rùbà wọn lójú pẹ̀lú ìjì rẹ.16Fi ìtìjú kún ojú wọn,kí àwọn ènìyàn bá à lè ṣe àfẹ́rí orúkọ rẹ àti kí o fi ìjì líle rẹ dẹ́rùbà, ìwọ Olúwa.17Jẹ́ kí ojú kí ó tì wọ́n, kí wọ́n sì dààmú láéláékí wọ́n ṣègbé sínú ẹ̀gàn18jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ìwọ, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa:pé ìwọ nìkan ní Ọ̀gá-ògo jùlọ lórí gbogbo ayé.