Saamu82yor_bib

Saamu ti Asafu.

1Ọlọ́run ń ṣàkóso nínú ìpéjọpọ̀ ńlá,ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn “ọlọ́run òrìṣà”.
2“Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa gbèjà àwọn aláìṣòdodokí ó sì ṣe ojú ìṣáájú sí àwọn ènìyàn búburú?3Gbèjà àwọn aláìlágbára àti aláìní baba;ṣe ìtọ́jú ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ẹni ìnilára.4Gba àwọn aláìlágbára àti aláìní;gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú.
5“Wọn kò mọ̀ ohun kankan,wọn kò lóye ohun kankan.Wọn ń rìn kiri nínú òkùnkùn;à si mí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé.
6“Mo wí pé, ‘Ẹyin ní “Ọlọ́run òrìṣà”;ẹ̀yin ní gbogbo ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ.’7Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ó kú bí ènìyàn lásán;ẹ̀yin ó ṣubú bí ọ̀kan nínú ọmọ-aládé.”
8Dìde, Ọlọ́run, ṣe ìdájọ́ ayé,nítorí gbogbo orílẹ̀-èdè ni ìní rẹ.