Saamu79yor_bib

Saamu ti Asafu.

1Ọlọ́run, àwọn orílẹ̀-èdè ti wá ilẹ̀ ìní rẹ;wọ́n ti ba tẹmpili mímọ́ rẹ jẹ́,wọn di Jerusalẹmu kù sí òkìtì àlàpà.2Wọn ti fi ara òkú àwọn ìránṣẹ́ rẹfún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní oúnjẹ,ẹran-ara àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ fún ẹranko ilẹ̀.3Wọ́n tu ẹ̀jẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí omiyí Jerusalẹmu ká,kò sì ṣí àwọn tí yóò sìn wọ́n.4Àwa di ohun ẹ̀gàn sí àwọn tí ó yí wa ká,àbùkù àti ìfiṣe ẹlẹ́yà sí àwọn tí ó yí wa ká.
5Nígbà wo, Olúwa? Ní ìwọ ó máa bínú títí láé?Yóò ti pẹ́ tó ti owú rẹ yóò ha jò bí iná?6Tú ìbínú rẹ jáde sí orílẹ̀-èdètí kò ní ìmọ̀ rẹ,lórí àwọn ìjọbatí kò pe orúkọ rẹ;7nítorí wọ́n ti run Jakọbuwọ́n sì sọ ibùgbé rẹ di ahoro.
8Má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wa sí wa lọ́rùnjẹ́ kí àánú rẹ wá kánkán láti bá wa,nítorí tí a rẹ̀ wá sílẹ̀ gidigidi.9Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọ́run Olùgbàlà wa,fún ògo orúkọ rẹ;gbà wá kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnítorí orúkọ rẹ.10Àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa wí pé,“Níbo ni Ọlọ́run wọn wà?”Ní ojú wa, kí a mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdèkí ó sì gbẹ̀san àwọn ẹ̀jẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ tí a tú jáde.11Jẹ́ kí ìmí ẹ̀dùn oǹdè náà wá síwájú rẹ,gẹ́gẹ́ bí títóbi agbára rẹìwọ ṣe ìtọ́jú àwọn ti a dá lẹ́bi ikú.12San án padà sí àyà àwọn aládùúgbò wa nígbà méjenípa ẹ̀gàn tí wọn ti gàn ọ́ Olúwa.13Nígbà náà àwa ènìyàn rẹ,àti àgùntàn pápá rẹ,yóò fi ọpẹ́ fún ọ títí láé;láti ìran dé ìranni àwa ó fi ìyìn rẹ hàn.