Saamu76yor_bib

Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Asafu. Orin.

1Ní Juda ni a mọ Ọlọ́run;orúkọ rẹ̀ sì lágbára ní Israẹli2Àgọ́ rẹ̀ wà ní Salẹmu,ibùgbé rẹ̀ ni Sioni.3Níbẹ̀ ni ó ṣẹ́ ọfà,asà àti àwọn idà, ohun ìjà ogun. Sela.
4Ìwọ ni ògo àti ọlá,ju òkè ńlá ìkógun wọ̀nyí lọ.5A kó àwọn alágídí ọkàn ní ìkógunwọ́n sun oorun ìgbẹ̀yìn wọn;kò sí ọ̀kan nínú àwọn akọnitó lè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè.6Ní ìfibú rẹ, Ọlọ́run Jakọbu,àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀.
7Ìwọ nìkan ni ó yẹ kí a bẹ̀rù.Ta ló lé dúró níwájú rẹ, nígbà tí ìwọ bá ń bínú?8Ìwọ ń ṣe ìdájọ́ láti ọ̀run,ilé ayé bẹ̀rù, ó sì dúró jẹ́ẹ́,9nígbà tí, ìwọ Ọlọ́run,bá dìde láti ṣe ìdájọ́,láti gba àwọn ẹni ìnilára ilẹ̀ náà. Sela.10Lóòótọ́, ìbínú rẹ sí àwọn ènìyàn ń mú ìyìn wá fún ọ,ẹni tí ó yọ nínú ìbínú rẹ ní a dá nígbà tí ìwọ bá fi ìbínú ìyókù di ara rẹ ni àmùrè.
11Jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì mú un ṣẹ;kí gbogbo àwọn tí ó yí i kámú ẹ̀bùn wá fún ẹni tí ó tọ́ láti bẹ̀rù.12Ó ké ẹ̀mí àwọn aládé kúrò;àwọn ọba ayé sì ń bẹ̀rù rẹ̀.