Saamu75yor_bib
Fún adarí orin. Tí ohùn, “Má ṣe parun.” Saamu ti Asafu. Orin.
1A fi ìyìn fún ọ, Ọlọ́run,a yìn ọ́, nítorí orúkọ rẹ súnmọ́ tòsí;àwọn ènìyàn ń sọ ti ìyanu rẹ.2Ìwọ wí pé, “Mo yan àkókò ìyàsọ́tọ̀;Èmi ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ òdodo.3Nígbà tí ayé àti àwọn ènìyàn ibẹ̀ wárìrì,Èmi ni mo di òpó rẹ̀ mú ṣinṣin.4Èmí wí fún àwọn agbéraga pé,ẹ má ṣe gbéraga mọ́;àti sí ènìyàn búburú;ẹ má ṣe gbé ìwo yín sókè.5Ẹ má ṣe gbe ìwo yín sókè sí ọ̀run;ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọrùn líle.”6Nítorí ìgbéga kò ti ìlà-oòrùn wátàbí ní ìwọ̀-oòrùn,bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe láti gúúsù wá.7Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni olùdájọ́;Ó ń rẹ ẹnìkan sílẹ̀, ó sì ń gbé ẹlòmíràn ga.8Ní ọwọ́ Olúwa ni ago kan wà,ọtí wáìnì náà sì pọ́n, ó kún fún àdàlú,ó fún ọtí àdàlú tí a pò mọ́ òórùn dídùn tí ó tú jáde,àwọn ènìyàn búburú ayé gbogbo mú u pátápátá.9Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn rẹ títí láé;èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jakọbu.10Èmi ó gé ìwo gbogbo ènìyàn búburú,ṣùgbọ́n ìwo àwọn olódodo ni a ó gbéga.