Saamu70yor_bib
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Ẹ̀bẹ̀.
1Yára, Ọlọ́run, láti gbà mí là,Olúwa, wá kánkán láti ràn mí lọ́wọ́.2Kí àwọn tí ń wá ọkàn mikí a dójútì wọ́n, kí wọn sì dààmú;kí àwọn tó ń wá ìparun miyí ẹ̀yìn padà nínú ìtìjú.3Kí a pa wọ́n ní ẹ̀yìn dà fún èrèìtìjú àwọn tí ń wí pé, “Háà! Háà!”4Ṣùgbọ́n kí àwọn tí ó ń wá ọ ó máa yọ̀kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa rẹ,kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà rẹ máa wí pé,“Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga!”5Ṣùgbọ́n mo jẹ́ òtòṣì àti aláìní;wa kánkán sí ọ̀dọ̀ mi, Ọlọ́run.Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àti olùdáǹdè mi;Olúwa, má ṣe dúró pẹ́.