Saamu67yor_bib
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu. Orin.
1Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa kí ó sì bùkún fún wa,kí ó sì jẹ́ kí ojú rẹ̀ tàn yí wa ká,2kí ọ̀nà rẹ le di mí mọ̀ ní ayé,ìgbàlà rẹ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.3Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́!4Kí orílẹ̀-èdè kí ó yọ̀, kí ó sì kọrin fún ayọ̀,nítorí ìwọ fi òdodo darí àwọn ènìyàn,ìwọ sì jẹ ọba àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé.5Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́. Sela.6Nígbà náà ní ilẹ̀ yóò mú ìkórè rẹ̀ wá, Ọlọ́run,Ọlọ́run wa, yóò bùkún fún wa.7Ọlọ́run yóò bùkún fún wa,àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò sì máa bẹ̀rù rẹ̀.