Saamu63yor_bib
Saamu ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú aginjù Juda.
1Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi,nígbà gbogbo ni mo ń ṣàfẹ́rí rẹ,òǹgbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi,ara mi fà sí ọ,ní ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tí ń ṣàárẹ̀níbi tí kò sí omi.2Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́,mo rí agbára àti ògo rẹ.3Nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ayé lọ,ètè mi yóò fògo fún ọ.4Èmi ó yìn ọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè,èmi ó gbé ọwọ́ sókè, èmi ó sì pe orúkọ rẹ.5A ó tẹ́ ọkàn mi lọ́rùn bí ọlọ́ràá oúnjẹ;pẹ̀lú ètè ìyìn, ẹnu mi yóò yìn ọ́.6Nígbà tí mo rántí rẹ lórí ibùsùn mi;èmi ń ronú rẹ títí ìṣọ́ òru.7Nítorí ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi,mo kọrin níbi òjìji ìyẹ́ apá rẹ.8Ọkàn mí fà sí ọ:ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbé mi ró.9Àwọn tí ó ń wá ọkàn mí ni a ó parun;wọn ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé.10Wọn ó ti ọwọ́ idà ṣubúwọn ó sì di jíjẹ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀.11Ṣùgbọ́n ọba yóò yọ̀ nínú Ọlọ́runẹni tí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra yóò ṣògoṣùgbọ́n ẹnu àwọn òpùrọ́ la ó pamọ́.