Saamu61yor_bib

Fún adarí orin. Ohun èlò orin olókùn. Ti Dafidi.

1Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run;tẹ́tí sí àdúrà mi.
2Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́,mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀;mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ.3Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi,ilé ìṣọ́ agbára àwọn ọ̀tá.
4Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ rẹ títí láékí n sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá rẹ.5Nítorí ìwọ ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi, Ọlọ́run;Ìwọ ti fún mi ní ogún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ.
6Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn,ọdún rẹ̀ fún ìrandíran.7Kí ó máa jẹ ọba níwájú Ọlọ́run títí láé;pèsè àánú àti òtítọ́ rẹ tí yóò máa ṣe ìtọ́jú rẹ.
8Nígbà náà ni èmi ó máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ títí láékí n san ẹ̀jẹ́ mi ní ojoojúmọ́.