Saamu58yor_bib

Fún adarí orin. Tí ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu.

1Ẹ̀yin ha ń sọ òdodo nítòótọ́ẹ̀yin ìjọ ènìyàn?Ǹjẹ́ ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ tí ó ṣe títọ́ẹ̀yìn ọmọ ènìyàn?2Bẹ́ẹ̀ kọ́, nínú ọkàn yín ẹ̀yìn ń gbèrò àìṣòdodo,ọwọ́ yín sì tú ìwà ipá jáde ni ayé.
3Ní inú ìyá wọn wá ni ènìyàn búburú tí ṣìnà,lójúkan náà tí a ti bí wọn, wọn a máa ṣèké.4Oró wọn dàbí oró ejò,wọn dàbí adití ejò paramọ́lẹ̀ tí ó di ara rẹ̀ ni etí,5tí kò ní gbọ́ ìpè àwọn atunilójú,bí ó ti wù kí ó máa fi ọgbọ́n ṣe ìtujú tó.
6Ká eyín ẹnu wọn, Ọlọ́run;ní ẹnu wọn,ká ọ̀gàn àwọn ọmọ kìnnìún, Olúwa.7Jẹ́ kí wọn parẹ́ bí omi tó ń sàn lọ;nígbà tí ó bá fa ọfà rẹ̀, kí ọ̀kọ̀ wọn kí ó ṣẹ́.8Jẹ́ kí wọn rí bí ìgbín tí rẹ̀ dànù tí ó sì ṣègbébí ọmọ tí oṣù rẹ̀ kò pé, kí wọn má ṣe rí oòrùn.
9Kí ìkòkò yín kí ó tó mọ ìgbóná ẹ̀gún;bóyá ní tútù tàbí ní gbígbẹ, yóò fi ìjì gbá wọn lọ.10Olódodo yóò yọ̀ nígbà a bá ń gbẹ̀san wọn,nígbà tí wọn bá wẹ ẹsẹ̀ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn búburú.11Àwọn ènìyàn yóò wí pé,“Lóòtítọ́ èrè àwọn ń bẹ fún olódodo;lóòtítọ́ òun ni Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ ní ayé.”