Saamu52yor_bib

Fún adarí orin. Maskili ti Dafidi. Nígbà tí Doegi ará Edomu tọ Saulu lọ láti sọ fún pé, “Dafidi wà ní ilé Ahimeleki.”

1Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe féfé nínú ìwà ìkà, ìwọ alágbára ọkùnrin?Èéṣe tí ìwọ fi ń gbéraga nígbà gbogbo,ìwọ ẹni ẹ̀gàn níwájú Ọlọ́run?2Ahọ́n rẹ̀ ń gbìmọ̀ ìparun;ó dàbí abẹ mímú,ìwọ ẹni tí ń hùwà ẹ̀tàn.3Ìwọ fẹ́ràn ibi ju ìre lọ,àti èké ju kí ó sọ òtítọ́ lọ.4Ìwọ fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ìpanilára gbogbo,ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn!
5Ọlọ́run yóò sì lù ọ́ bolẹ̀ láéláé,yóò sì dì ọ́ mú,yóò sì já ọ kúrò ni ibùjókòó rẹ,yóò sì fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè. Sela.6Àwọn olódodo yóò rí, wọn yóò sì bẹ̀rùwọn yóò sì rẹ́rìn-ín rẹ̀, wí pé,7“Èyí ni ọkùnrin náà ti kò fi Ọlọ́run ṣe agbára rẹ̀,bí kò ṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ ni ó gbẹ́kẹ̀lé,ó sì mu ara rẹ̀ le nínú ìwà búburú rẹ̀.”
8Ṣùgbọ́n èmi dàbí igi Olifití ó gbilẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run;èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í kùnàláé àti láéláé.9Èmi yóò yìn ọ títí fún ohun tí ó ti ṣe;èmi ní ìrètí nínú orúkọ rẹ,nítorí orúkọ rẹ dára.Èmi yóò yìn ọ́ níwájú àwọn ènìyàn mímọ́.