Saamu48yor_bib

Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora.

1Ẹni ńlá ní Olúwa, tí ó sì yẹ láti máa yìnní ìlú Ọlọ́run wa, lórí òkè mímọ́ rẹ̀.
2Ó dára nínú ipò ìtẹ́ rẹ̀,ayọ̀ gbogbo ayé,òkè Sioni, ní ìhà àríwání ìlú ọba ńlá.3Ọlọ́run wà nínú ààbò ààfin rẹ̀;ó fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ odi alágbára.
4Nígbà tí àwọn ọba kógun jọ pọ̀,wọ́n jùmọ̀ ń kọjá lọ.5Wọn rí i, bẹ́ẹ̀ ni ẹnu sì yà wọ́n,a yọ wọ́n lẹ́nu, wọ́n yára lọ.6Ẹ̀rù sì bà wọ́n níbẹ̀,ìrora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrọbí.7Ìwọ bà wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ orí omi Tarṣiṣi,wọ́n fọ́nká láti ọwọ́ ìjì ìlà-oòrùn.
8Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́,bẹ́ẹ̀ ni àwa rí,ní inú Olúwa àwọn ọmọ-ogunní ìlú Ọlọ́run wa,Ọlọ́run jẹ́ kí ó wà ní abẹ́ ààbò títí láéláé. Sela.
9Láàrín tẹmpili rẹ, Ọlọ́run,àwa ti ń sọ ti ìṣeun ìfẹ́ rẹ.10Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ Ọlọ́run,ìyìn rẹ̀ dé òpin ayé,ọwọ́ ọ̀tún rẹ kún fún òdodo.11Jẹ́ kí òkè Sioni kí ó yọ̀kí inú àwọn ọmọbìnrin Juda kí ó dùnnítorí ìdájọ́ rẹ.
12Rìn Sioni kiri lọ yíká rẹ̀,ka ilé ìṣọ́ rẹ̀.13Kíyèsi odi rẹ̀,kíyèsi àwọn ààfin rẹ̀kí ẹ̀yin lè máa wí fún ìran tí ń bọ̀.
14Nítorí Ọlọ́run yìí Ọlọ́run wà ní títí ayé,Òun ni yóò ṣe amọ̀nà wa títí dè òpin ayé.