Saamu47yor_bib
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.
1Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyànẹ hó sí Ọlọ́run pẹ̀lú orin ayọ̀ tó rinlẹ̀.2Báwo ni Olúwa Ọ̀gá-ògo ti ní ẹ̀rù tóọba ńlá lórí gbogbo ayé.3Ṣe ìkápá àwọn orílẹ̀-èdè lábẹ́ waàwọn ènìyàn lábẹ́ ẹsẹ̀ wa4Ó mú ilẹ̀ ìní wa fún wa,ọlá Jakọbu, ẹni tí ó fẹ́ wa.5Ọlọ́run tó gòkè lọ tí òun tayọ̀,Olúwa ti òun ti ariwo ìpè.6Ẹ kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, ẹ kọrin ìyìn.Ẹ kọrin ìyìn sí ọba wa, ẹ kọrin ìyìn!7Nítorí Ọlọ́run ni ọba gbogbo ayé,ẹ kọrin ìyìn pẹ̀lú Saamu!8Ọlọ́run jẹ ọba lórí gbogbo kèfèrí;Ọlọ́run jókòó lórí ìtẹ́ ìwà mímọ́ rẹ̀.9Àwọn aládé ayé kó ara wọn jọgẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run Abrahamunítorí asà ayé ti Ọlọ́run ni,òun ni ó ga jùlọ.