Saamu46yor_bib
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Gẹ́gẹ́ bí ti alamoti. Orin.
1Ọlọ́run ni ààbò àti agbára waó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.2Nítorí náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ ṣí ayé ní ìdí,tí òkè sì ṣubú sínú Òkun.3Tí omi rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mìtí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀. Sela.4Odò ńlá kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ mú inú ìlú Ọlọ́run dùn,ibi mímọ́, níbi ti Ọ̀gá-ògo ń gbé.5Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, kò ní yẹ̀:Ọlọ́run yóò ràn án lọ́wọ́ ní kùtùkùtù òwúrọ̀.6Àwọn orílẹ̀-èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba ṣubú,ó gbé ohun rẹ̀ sókè, ayé yọ̀.7Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa,Ọlọ́run Jakọbu ni ààbò wa.8Ẹ wá wo iṣẹ́ Olúwairú ahoro tí ó ṣe ní ayé.9O mú ọ̀tẹ̀ tán de òpin ilẹ̀ ayéó ṣẹ́ ọrun, ó sì gé ọ̀kọ̀ sí méjìó fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná.10Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run.A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè,a ó gbé mi ga ní ayé.11Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa;Ọlọ́run Jakọbu sì ni ààbò wa.