Saamu41yor_bib
Fún adarí orin. Saamu Dafidi.
1Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ń ro ti aláìní:Olúwa yóò gbà á ní ìgbà ìpọ́njú.2Olúwa yóò dáàbò bò ó yóò sì pa ọkàn rẹ̀ mọ́:yóò bùkún fún un ní orí ilẹ̀kò sì ní fi sílẹ̀ fún ìfẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.3Olúwa yóò gbà á lórí àkéte àìsàn rẹ̀yóò sì mú un padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn rẹ̀.4Ní ti èmi, mo wí pé “Olúwa, ṣàánú fún mi;wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ”.5Àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi nínú àrankàn, pé,“Nígbà wo ni yóò kú, ti orúkọ rẹ̀ yóò sì run?”6Nígbàkígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí,wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara rẹ̀;nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kálẹ̀.7Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi;èmi ni wọ́n ń gbìmọ̀ ibi sí,8wọ́n wí pé, “Ohun búburú ni ó dì mọ́ ọn ṣinṣinàti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí,kì yóò dìde mọ́.”9Pàápàá, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé,ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi,tí gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè sí mi.10Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa, ṣàánú fún mi;gbé mi sókè, kí ń ba lè san fún wọn.11Èmi mọ̀ pé inú rẹ̀ dùn sí mi,nítorí ọ̀tá mi kò borí mi.12Bí ó ṣe tèmi niìwọ dì mímú nínú ìwà òtítọ́ miìwọ sì gbé mi kalẹ̀ níwájú rẹ títí láé.13Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli,láé àti láéláé.Àmín àti Àmín.