Saamu39yor_bib

Fún adarí orin. Fún Jedutuni. Saamu Dafidi.

1Mo wí pé, “Èmi yóò ṣọ́ ọ̀nà mikí èmi kí ó má fi ahọ́n mi ṣẹ̀;èmi yóò fi ìjánu kó ara mi ní ẹnuníwọ̀n ìgbà tí ènìyàn búburú bá ń bẹ ní iwájú mi.”2Mo fi ìdákẹ́ ya odi;mo tilẹ̀ pa ẹnu mi mọ́ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rere;ìbànújẹ́ mi sì pọ̀ sí i.3Àyà mi gbóná ní inú mi.Nígbà tí mo ń ṣàṣàrò, iná ràn;nígbà náà ni mo fi ahọ́n mi sọ̀rọ̀:
4“Olúwa, jẹ́ kí èmi kí ó mọ òpin mi,àti ìwọ̀n ọjọ́ mi, bí ó ti ríkí èmi kí o le mọ ìgbà tí mó ní níhìn-ín.5Ìwọ ti ṣe ayé mibí ìbú àtẹ́lẹwọ́,ọjọ́ orí mi sì dàbí asánní iwájú rẹ.Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínúìjókòó rere rẹ̀ jásí asán pátápátá. Sela.
6“Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji.Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán;wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ,wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ.
7“Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí,Olúwa,kín ni mo ń dúró dè?Ìrètí mí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ rẹ.8Gbà mí lọ́wọ́ ìrékọjá mi gbogbo.Kí o má sì sọ mí di ẹni ẹ̀gànàwọn ènìyàn búburú.9Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́;èmi kò sì ya ẹnu mi,nítorí wí pé ìwọ ni ó ṣe é.10Mú pàṣán rẹ kúrò ní ara mi;èmí ṣègbé tán nípa lílù ọwọ́ rẹ.11Ìwọ fi ìbáwí kìlọ̀fún ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀,ìwọ a mú ẹwà rẹ parunbí kòkòrò aṣọ;nítòótọ́ asán ni ènìyàn gbogbo.
12“Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa,kí o sì fetí sí igbe mi;kí o má ṣe di etí rẹ sí ẹkún mi.Nítorí àlejò ni èmi lọ́dọ̀ rẹ,àti àtìpó, bí gbogbo àwọn baba mi ti rí.13Dá mi sí, kí èmi lè ní agbára,kí èmi tó lọ kúrò níhìn-ín yìí,àti kí èmi ó tó ṣe aláìsí.”