Saamu34yor_bib
Tí Dafidi. Nígbà tí ó díbọ́n bí ẹni tí ń ṣe wèrè níwájú Abimeleki, ẹni tí ó lé e lọ, ó sì jáde lọ.
1Èmi yóò máa fi ìbùkún fún Olúwa nígbà gbogbo;ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé.2Ọkàn mí yóò máa ṣògo nínú Olúwa;jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ gbọ́ kí inú wọn kí ó sì máa dùn.3Gbé Olúwa ga pẹ̀lú mi;kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ lékè.4Èmi wá Olúwa, ó sì dá mi lóhùn;Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo.5Wọ́n wò ó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn;ojú kò sì tì wọ́n.6Ọkùnrin olùpọ́njú yí kígbe, Olúwa sì gbóhùn rẹ̀;ó sì gbà á là kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.7Angẹli Olúwa yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ káó sì gbà wọ́n.8Tọ́ ọ wò kí o sì rí i wí pé Olúwa dára;ẹni ayọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ààbò nínú rẹ̀.9Ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́,nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.10Àwọn ọmọ kìnnìún a máa ṣe aláìní ebi a sì máa pa wọ́n;ṣùgbọ́n àwọn tí ó wá Olúwa kì yóò ṣe aláìní ohun tí ó dára.11Wá, ẹ̀yin ọmọ mi, fi etí sí mi;èmi yóò kọ́ ọ yín ní ẹ̀rù Olúwa.12Ta ni nínú yín tí ń fẹ́ ìyè, tí ó sì ń fẹ́ ọjọ́ púpọ̀;kí ó lè gbádùn ọjọ́ rere?13Pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibiàti ètè rẹ̀ kúrò ní ẹ̀tàn sísọ.14Yà kúrò nínú ibi kí o sì ṣe rere;wá àlàáfíà, kí o sì lépa rẹ̀.15Ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo;etí i rẹ̀ sì ṣí sí ẹkún wọn.16Ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú;láti ké ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.17Nígbà tí olódodo bá ké fún ìrànlọ́wọ́,Olúwa a máa gbọ́, a sì yọ wọ́n jáde láti inú gbogbo wàhálà wọn.18Olúwa súnmọ́ etí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn;ó sì gba irú àwọn tí í ṣe oníròra ọkàn là.19Ìpọ́njú àwọn olódodo pọ̀,ṣùgbọ́n Olúwa gbà wọ́n kúrò nínú gbogbo rẹ̀.20Ó pa gbogbo egungun wọn mọ́;kò sí ọ̀kan tí ó dá nínú wọn.21Ibi ni ó mú ikú ìkà wá,àti àwọn tí ó kórìíra olódodo ni yóò jẹ̀bi.22Olúwa ra ọkàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ padà;kò sí ọ̀kan nínú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé tí yóò jẹ̀bi.