Saamu33yor_bib

1Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin olódodo;ìyìn si yẹ fún ẹni dídúró ṣinṣin.2Ẹ yin Olúwa pẹ̀lú dùùrù;ẹ máa fi ohun èlò olókùn mẹ́wàá kọrin sí i.3Ẹ kọ orin tuntun sí i;ẹ máa fi ọgbọọgbọ́n lu ohun èlò orin sí i, pẹ̀lú ariwo.
4Nítorí pé ọ̀rọ̀ Olúwa dúró ṣinṣin,gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ni à ń ṣe nínú òtítọ́.5Ó fẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́;ilé ayé kún fún ìdúró ṣinṣin àti àánú Olúwa.
6Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ṣe dá àwọn ọ̀run,àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun wọn nípa ìmísí ẹnu rẹ̀.7Ó kó àwọn omi òkun jọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú ìgò;ó sì fi ibú ṣe ilé ìṣúra gbogbo.8Jẹ́ kí gbogbo ayé kí ó bẹ̀rù Olúwa:jẹ́ kí gbogbo àwọn olùgbé ayé kí ó wà nínú ìbẹ̀rù rẹ̀.9Nítorí tí ó sọ̀rọ̀, ó sì ti rí bẹ́ẹ̀;ó pàṣẹ ó sì dúró ṣinṣin.
10Olúwa ti mú ìmọ̀ràn àwọn orílẹ̀-èdè wá sí asán;ó sì mú àrékérekè àwọn ènìyàn di ṣíṣákì í.11Ìgbìmọ̀ Olúwa dúró títí ayérayé,àní ìrò inú rẹ̀ láti ìrandíran ni.
12Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè náà, Ọlọ́run ẹni tí Olúwa jẹ́ tirẹ̀,àti àwọn ènìyàn náà tí ó ti yàn ṣe ìní rẹ̀.13Olúwa wò láti ọ̀run wá;Ó sì rí gbogbo ìran ènìyàn.14Níbi tí ó ti jókòó lórí ìtẹ́Ó wo gbogbo àwọn olùgbé ayé15ẹni tí ó ṣe àyà wọn bákan náà,ó sì kíyèsi ìṣe wọn.
16A kò gba ọba kan là nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ogun;kò sì sí jagunjagun tí a gbà sílẹ̀ nípa agbára ńlá rẹ̀.17Ohun asán ni ẹṣin fún ìṣẹ́gun;bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi agbára ńlá rẹ̀ gbani sílẹ̀.18Wò ó, ojú Olúwa wà lára àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,àti lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú ìfẹ́ rẹ̀ tí ó dúró ṣinṣin.19Láti gba ọkàn wọn kúrò lọ́wọ́ ikúàti láti pa wọ́n mọ́ láààyè lọ́wọ́ ìyàn.
20Ọkàn wa dúró de Olúwa;òun ni ìrànlọ́wọ́ wa àti asà wa.21Ọkàn wa yọ̀ nínú rẹ̀,nítorí pé, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ rẹ mímọ́.22Kí àánú rẹ, Olúwa, kí ó wà lára wa,àní gẹ́gẹ́ bí àwa ti ń ṣe ìrètí nínú rẹ.