Saamu32yor_bib

Ti Dafidi. Maskili.

1Ìbùkún ni fún àwọntí a dárí ìrékọjá wọn jì,tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.2Ìbùkún ni fún ọkùnrin náàẹni tí Olúwa kò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí i lọ́rùnàti nínú ẹ̀mí ẹni tí kò sí ẹ̀tàn.
3Nígbà tí mo dákẹ́,egungun mi di gbígbó dànùnípa ìkérora mi ní gbogbo ọjọ́.4Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òruọwọ́ rẹ̀ wúwo sí mi lára;agbára mi gbẹ tángẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn. Sela.
5Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọàti pé èmi kò sì fi àìṣòdodo mi pamọ́.Èmi wí pé, “Èmi yóò jẹ́wọ́ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Olúwa,”ìwọ sì dáríẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. Sela.
6Nítorí náà jẹ́ kí gbogbo àwọn olódodo máa gbà àdúrà sí ọní ìgbà tí a lè rí ọ;nítòótọ́ nígbà tí ìṣàn omi ńlá bá ru sókè,wọn kì yóò lè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀.7Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi;ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu;ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka. Sela.
8Èmi yóò kọ́ ọ, èmi yóò sì fi ẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà tí ìwọ yóò rìnèmi yóò máa gbà ọ́ ní ìyànjú, èmi yóò sì máa fi ojú mi tọ́ ọ.9Má ṣe dàbí ẹṣin tàbí ìbáaka,tí kò ní òyeẹnu ẹni tí a gbọdọ̀ fi ìjánu bọ̀,kí wọn má ba à súnmọ́ ọ.10Ọ̀pọ̀ ìkáàánú ní yóò wà fún ènìyàn búburú,ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa tí ó dúró ṣinṣinni yóò yí àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ká.
11Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, kí ẹ sì ní inú dídùn, ẹ̀yìn olódodo;ẹ sì máa kọrin, gbogbo ẹ̀yìn tí àyà yín dúró ṣinṣin.