Saamu31yor_bib

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

1Nínú rẹ̀, Olúwa ni mo ti rí ààbò;má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí;gbà mí nínú òdodo rẹ.2Tẹ́ etí rẹ sí mi,gbà mí kíákíá;jẹ́ àpáta ààbò mi,jẹ́ odi alágbára láti gbà mí.3Ìwọ pàápàá ni àpáta àti ààbò mi,nítorí orúkọ rẹ, máa ṣe olùtọ́ mi, kí o sì ṣe amọ̀nà mi.4Yọ mí jáde kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ fún mi,nítorí ìwọ ni ìsádi mi.5Ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé;ìwọ ni o ti rà mí padà, Olúwa, Ọlọ́run òtítọ́.
6Èmi ti kórìíra àwọn ẹni tí ń fiyèsí òrìṣà tí kò níye lórí;ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.7Èmi yóò yọ̀, inú mi yóò dùn nínú ìfẹ́ ńlá rẹ,nítorí ìwọ ti rí ìbìnújẹ́ miìwọ ti mọ̀ ọkàn mi nínú ìpọ́njú.8Pẹ̀lú, ìwọ kò sì fà mi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ìwọ ti fi ẹsẹ̀ mi lé ibi ààyè ńlá.
9Ṣàánú fún mi, ìwọ Olúwa, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú;ojú mi fi ìbìnújẹ́ sùn,ọkàn àti ara mi pẹ̀lú.10Èmi fi ìbànújẹ́ lo ọjọ́ miàti àwọn ọdún mi pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn;agbára mi ti kùnà nítorí òsì mi,egungun mi sì ti rún dànù.11Èmi di ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ọ̀tá mi gbogbo,pẹ̀lúpẹ̀lú láàrín àwọn aládùúgbò mi,mo sì di ẹ̀rù fún àwọn ojúlùmọ̀ mi;àwọn tí ó rí mi ní òde ń yẹra fún mi.12Èmi ti di ẹni ìgbàgbé kúrò ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti kú;èmi sì dàbí ohun èlò tí ó ti fọ́.13Nítorí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpayà tí ó yí mi ká;tí wọn gbìmọ̀ pọ̀ sí mi,wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí miláti gba ẹ̀mí mi.
14Ṣùgbọ́n èmí gbẹ́kẹ̀lé ọ, ìwọ Olúwa;mo sọ wí pé, “Ìwọ ní Ọlọ́run mi.”15Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;gbà mí kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá miàti àwọn onínúnibíni.16Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ lára;gbà mí nínú ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.17Má ṣe jẹ́ kí ojú ki ó tì mí, Olúwa;nítorí pé mo ké pè ọ́;jẹ́ kí ojú kí ó ti ènìyàn búburú;jẹ́ kí wọ́n lọ pẹ̀lú ìdààmú sí isà òkú.18Jẹ́ kí àwọn ètè irọ́ kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́,pẹ̀lú ìgbéraga àti ìkẹ́gàn,wọ́n sọ̀rọ̀ àfojúdi sí olódodo.
19Báwo ni títóbi oore rẹ̀ ti pọ̀ tó,èyí tí ìwọ ti ní ní ìpamọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,èyí tí ìwọ rọ̀jò rẹ̀ níwájú àwọn ènìyàntí wọ́n fi ọ́ ṣe ibi ìsádi wọn.20Ní abẹ́ ìbòòji iwájú rẹ ni ìwọ pa wọ́n mọ́ síkúrò nínú ìdìmọ̀lù àwọn ènìyàn;ní ibùgbé rẹ, o mú wọn kúrò nínú ewukúrò nínú ìjà ahọ́n.
21Olùbùkún ni Olúwa,nítorí pé ó ti fi àgbà ìyanu ìfẹ́ tí ó ní sí mi hàn,nígbà tí mo wà ní ìlú tí wọ́n rọ̀gbà yíká.22Èmí ti sọ nínú ìdágìrì mi,“A gé mi kúrò ní ojú rẹ!”Síbẹ̀ ìwọ ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún àánúnígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.
23Ẹ fẹ́ Olúwa, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́!Olúwa pa olódodo mọ́,ó sì san án padà fún agbéraga ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.24Jẹ́ alágbára, yóò sì mú yín ní àyà legbogbo ẹ̀yin tí ó dúró de Olúwa.