Saamu3yor_bib
Saamu ti Dafidi. Nígbà ti ó sá fún ọmọ rẹ̀ Absalomu.
1Olúwa, báwo ni àwọn ọ̀tá mi ṣe pọ̀ tó báyìí!Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó!2Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé“Ọlọ́run kò nígbà á là.” Sela.3Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, Olúwa;ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.4Olúwa ni mo kígbe sókè sí,ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela.5Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn;mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró.6Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàntí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.7Dìde, Olúwa!Gbà mí, Ọlọ́run mi!Lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi ní àgbọ̀n;kí o sì ká eyín àwọn ènìyàn búburú.8Láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìgbàlà ti wá.Kí ìbùkún rẹ wà lórí àwọn ènìyàn rẹ. Sela.