Saamu29yor_bib

Saamu ti Dafidi.

1Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run,ẹ fi fún Olúwa, ògo àti alágbára.2Fi fún Olúwa, àní ògo orúkọ rẹ̀;sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́.
3Ohùn Olúwa n ré àwọn omi kọjá;Ọlọ́run ògo sán àrá,Olúwa san ara.4Ohùn Olúwa ní agbára;ohùn Olúwa kún fún ọláńlá.5Ohùn Olúwa fa igi kedari;Olúwa náà ló fọ́ igi kedari Lebanoni ya.6Ó mú Lebanoni fo bí i ọmọ màlúù,àti Sirioni bí ọmọ àgbáǹréré.7Ohùn Olúwa ń yabí ọwọ́ iná mọ̀nà.8Ohùn Olúwa ń mi aginjù.Olúwa mi aginjù Kadeṣi.9Ohùn Olúwa ní ó lọ igi óákù, ó n mú abo àgbọ̀nrín bí,ó sì bọ́ igi igbó sí ìhòhò.Àti nínú tẹmpili rẹ̀ gbogbo ohùn wí pé, “Ògo!”
10Olúwa jókòó, Ó sì jẹ ọba lórí ìṣàn omi;Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba títí láéláé.11Kí Olúwa fi agbára fún àwọn ènìyàn rẹ̀;bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà.