Saamu2yor_bib
1Èéṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń dìtẹ̀,àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkíṣí asán?2Àwọn ọba ayé péjọpọ̀àti àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀sí Olúwa àti sí ẹni àmì òróró rẹ̀.3Wọ́n sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a fa ẹ̀wọ̀n wọn já,kí a sì ju ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ wọn nù.”4Ẹni tí ó gúnwà lórí ìtẹ́ lọ́run rẹ́rìn-ín;Olúwa fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.5Nígbà náà ni yóò bá wọn wí ní ìbínú rẹ̀yóò sì dẹ́rùbà wọ́n ní ìrunú rẹ̀, ó wí pé,6“Èmi ti fi ọba mi sí ipòlórí Sioni, òkè mímọ́ mi.”7Èmi yóò sì kéde ìpinnu Olúwa:Ó sọ fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi;lónìí, èmi ti di baba rẹ.8Béèrè lọ́wọ́ mi,Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè di ìní rẹ,òpin ilé ayé yóò sì jẹ́ ogún rẹ.9Ìwọ yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọnìwọ yóò sì rún wọn wómúwómú bí ìkòkò amọ̀.”10Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n;ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ ẹ̀yin alákòóso ayé.11Ẹ sin Olúwa pẹ̀lú ìbẹ̀rùẹ sì máa yọ̀ pẹ̀lú ìwárìrì.12Fi ẹnu ko ọmọ náà ní ẹnu, kí ó má ba à bínú,kí ó má ba à pa yín run ní ọ̀nà yín,nítorí ìbínú rẹ̀ lè ru sókè ní ẹ̀ẹ̀kan.Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó fi í ṣe ibi ìsádi wọn.