Saamu150yor_bib
1Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.Ẹ fi ìyìn fún Ọlọ́run ní ibi mímọ́ rẹ̀,ẹ yìn ín nínú agbára ọ̀run rẹ̀.2Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ agbára rẹ̀.Ẹ yìn ín fún títóbi rẹ̀ tí ó tayọ̀.3Ẹ fi ohùn ìpè yìn ín.Ẹ fi ohun èlò orin yìn ín.4Ẹ fi ohun èlò orin àti ijó yìn ínfi ohun èlò orin olókùn àti ìpè yìn ín,5Ẹ yìn ín pẹ̀lú aro olóhùn òkè,ẹ yìn ín lára aro olóhùn gooro.6Jẹ́ kí gbogbo ohun tí ó ní ẹ̀mí yin Olúwa.Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.