Saamu148yor_bib
1Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.Ẹ fi ìyìn fún Olúwa láti ọ̀run wá,ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga.2Ẹ fi ìyìn fún un,gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀,ẹ fi ìyìn fún un,gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀.3Ẹ fi ìyìn fún un,oòrùn àti òṣùpá.Ẹ fi ìyìn fún un,gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.4Ẹ fi ìyìn fún un,ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gígaàti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.5Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwanítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn6Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláéó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.7Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wáẹ̀yin ẹ̀dá inú òkun títóbiàti ẹ̀yin ibú òkun,8mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyínìdí omi àti àwọn ìkùùkuu,ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ,9òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèké,igi eléso àti gbogbo igi kedari,10àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìngbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́,11àwọn ọba ayé àti ènìyàn ayé gbogboàwọn ọmọ-aládé àti gbogbo àwọn onídàájọ́ ayé,12ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrinàwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé.13Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwanítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ní ọláògo rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run14Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn rẹ̀,ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Israẹli,àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.