Saamu144yor_bib
Ti Dafidi.
1Ìyìn sí Olúwa àpáta mi,ẹni tí ó kọ́ ọwọ́ mi fún ogun,àti ìka mi fún ìjà.2Òun ni Ọlọ́run ìfẹ́ mi àti odi alágbára mi,ibi gíga mi àti olùgbàlà mi, asà mi,ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé,ẹni tí ó tẹrí àwọn ènìyàn ba lábẹ́ mi.3Olúwa, kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣàníyàn fún un,tàbí ọmọ ènìyàn tí ìwọ fi ń ronú nípa rẹ̀?4Ènìyàn rí bí èmi;ọjọ́ rẹ̀ rí bí òjìji tí ń kọjá lọ.5Tẹ ọ̀run rẹ ba, Olúwa, kí o sì sọ̀kalẹ̀;tọ́ àwọn òkè ńlá wọn yóò sí rú èéfín.6Rán mọ̀nàmọ́ná kí ó sì fọ́n àwọn ọ̀tá ká;ta ọfà rẹ kí ó sì dà wọ́n rú.7Na ọwọ́ rẹ sílẹ̀ láti ibi gíga;gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewukúrò nínú omi ńlá:kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì.8Ẹnu ẹni tí ó kún fún èkéẹni tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jẹ́ ìrẹ́jẹ.9Èmi yóò kọ orin tuntun sí ọỌlọ́run; lára ohun èlò orinolókùn mẹ́wàá èmi yóòkọ orin sí ọ.10Òun ni ó fi ìgbàlà fún àwọn ọba,ẹni tí ó gba Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ idà ìpanilára.Lọ́wọ́ pípanirun.11Gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewukúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjìtí ẹnu wọn kún fún èké,tí ọwọ́ ọ̀tún wọn jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún èké.12Kí àwọn ọmọkùnrin wakí ó dàbí igi gbígbìn tí ó dàgbà ni ìgbà èwe wọn,àti ọmọbìnrin wa yóò dàbí òpó ilétí a ṣe ọ̀nà sí bí àfarawé ààfin.13Àká wa yóò kúnpẹ̀lú gbogbo onírúurú oúnjẹàgùntàn wa yóò pọ̀ si ní ẹgbẹ̀rún,ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní oko wa:14àwọn màlúù wa yóò ru ẹrù wúwokí ó má sí ìkọlù,kí ó má sí ìkólọ sí ìgbèkùn,kí ó má sí i igbe ìpọ́njú ní ìgboro wa.15Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà tí ó wà ní irú ipò bẹ́ẹ̀,ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà,tí ẹni tí Ọlọ́run Olúwa ń ṣe.