Saamu143yor_bib
Saamu ti Dafidi.
1Olúwa gbọ́ àdúrà mi,fetísí igbe mi fún àánú;nínú òtítọ́ àti òdodo rẹ, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi.2Má ṣe mú ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìdájọ́,nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láààyètí ó ṣe òdodo níwájú rẹ.3Ọ̀tá ń lépa mi,ó fún mi pamọ́ ilẹ̀;ó mú mi gbé nínú òkùnkùnbí àwọn tí ó ti kú ti pẹ́.4Nítorí náà ẹ̀mí mi ṣe rẹ̀wẹ̀sì nínú mi;ọkàn mi nínú mi ṣì pòruurù.5Èmi rántí ọjọ́ tí ó ti pẹ́;èmi ń ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹmo sì ṣe àkíyèsí ohun tí ọwọ́ rẹ ti ṣe.6Èmi na ọwọ́ mi jáde sí ọ:òǹgbẹ rẹ gbẹ ọkàn mi bí i ìyàngbẹ ilẹ̀. Sela.7Dá mi lóhùn kánkán, Olúwa;ó rẹ ẹ̀mí mi tán.Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lára mikí èmi má ba à dàbí àwọn tí ó lọ sínú ihò.8Mú mi gbọ́ ìṣeun ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀:nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé.Fi ọ̀nà tí èmi i bá rìn hàn mí,nítorí èmi gbé ọkàn mi sókè sí ọ.9Gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, Olúwa,nítorí èmi fi ara mi pamọ́ sínú rẹ.10Kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ rẹ,nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mijẹ́ kí ẹ̀mí rẹ dídáradarí mi sí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú.11Nítorí orúkọ rẹ, Olúwa, sọ mi di ààyè;nínú òdodo rẹ, mú ọkàn mi jáde nínú wàhálà.12Nínú ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà, ké àwọn ọ̀tá mi kúrò,run gbogbo àwọn tí ń ni ọkàn mi lára,nítorí pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ.