Saamu140yor_bib
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
1Olúwa, gbà mi lọ́wọ́ ọkùnrin búburú u nì,yọ mí lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nì,2ẹni tí ń ro ìwà búburú ní inú wọn;nígbà gbogbo ni wọ́n ń rú ìjà sókè sí mi.3Wọ́n ti pọ́n ahọ́n wọn bí ejò,oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ ní abẹ́ ètè wọn.4Olúwa, pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú;yọ mí kúrò lọ́wọ́ ọkùnrin ìkà a nìẹni tí ó ti pinnu rẹ̀ láti bi ìrìn mi ṣubú.5Àwọn agbéraga ti dẹkùn sílẹ̀ fún mi àti okùn:wọ́n ti na àwọ̀n lẹ́bàá ọ̀nà;wọ́n ti kẹ́kùn sílẹ̀ fún mi.6Èmi wí fún Olúwa pé ìwọ ni Ọlọ́run mi;Olúwa, gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.7Olúwa Olódùmarè, agbára ìgbàlà mi,ìwọ ni ó bo orí mi mọ́lẹ̀ ní ọjọ́ ìjà.8Olúwa, máa ṣe fi ìfẹ́ ènìyàn búburú fún un;má ṣe kún ọgbọ́n búburú rẹ̀ lọ́wọ́;kí wọn kí ó máa ba à gbé ara wọn ga. Sela.9Bí ó ṣe ti orí àwọn tí ó yí mi káàkiri ni,jẹ́ kí ète ìka ara wọn kí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀.10A ó da ẹ̀yin iná sí wọn lára,Òun yóò wọ́ wọn lọ sínú iná,sínú ọ̀gbun omi jíjìn,kí wọn kí ó má ba à le dìde mọ́.11Má ṣe jẹ́ kí aláhọ́n búburú fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ní ayé;ibi ni yóò máa dọdẹ ọkùnrin ìkà nì láti bì í ṣubú.12Èmi mọ̀ pé, Olúwa yóò mú ọ̀nà olùpọ́njú dúró,yóò sì ṣe ẹ̀tọ́ fún àwọn tálákà.13Nítòótọ́ àwọn olódodo yóòmáa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ;àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yóò máa gbé iwájú rẹ.