Saamu138yor_bib
Ti Dafidi.
1Èmi yóò yìn ọ́ tinútinú mi gbogbo;níwájú àwọn òrìṣà ni èmi ó kọrin ìyìn sí ọ.2Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀èmi ó sì máa yin orúkọ rẹnítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ;nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ rẹ lọ.3Ní ọjọ́ tí mo ké pè é ọ́, ìwọ dá mi lóhùn,ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi.4Gbogbo àwọn ọba ayé yóò yìn ọ́,Olúwa, ní ìgbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ.5Nítòótọ́, wọn ó máa kọrin ní ipa ọ̀nà Olúwa;nítorí pé ńlá ni ògo Olúwa.6Bí Olúwa tilẹ̀ ga, síbẹ̀ ó júbà àwọn onírẹ̀lẹ̀;ṣùgbọ́n agbéraga ni ó mọ̀ ní òkèrè réré.7Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di ààyè;ìwọ ó na ọwọ́ rẹ sí àwọn ọ̀tá mi,ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbà mí.8Olúwa yóò ṣe ohun tí ń ṣe tèmi láṣepé;Olúwa, àánú rẹ dúró láéláé;má ṣe kọ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ sílẹ̀.