Saamu137yor_bib
1Ní ẹ̀bá odò Babeli, níbẹ̀ ni àwa gbé jókòóàwa sì sọkún nígbà tí àwa rántí Sioni.2Àwa fi dùùrù wa kọ́ sí orí igi wílò,tí ó wà láàrín rẹ̀.3Nítorí pé níbẹ̀ ni àwọntí ó kó wa ní ìgbèkùn béèrè orin lọ́wọ́ wa,àti àwọn tí ó ni wá lára béèrè ìdárayá;wọn wí pé, “Ẹ kọ orin Sioni kan fún wa!”4Àwa ó ti ṣe kọ orinOlúwa ní ilẹ̀ àjèjì5Jerusalẹmu, bí èmi bá gbàgbé rẹjẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó gbàgbé ìlò rẹ̀.6Bí èmi kò bá rántí rẹ,jẹ́ kí ahọ́n mi kí ó lẹ̀ mọ́ èrìgì mi;bí èmi kò bá fi Jerusalẹmu ṣáájúolórí ayọ̀ mi gbogbo.7Olúwa rántí ọjọ́ Jerusalẹmu,lára àwọn ọmọ Edomu,àwọn ẹni tí ń wí pé,“Wó o palẹ̀, wó o palẹ̀ dé ìpìlẹ̀ rẹ̀!”8Ìwọ, ọmọbìnrin Babeli, ẹni tí a ó parun;ìbùkún ni fún ẹni tí ó san án fún ọbí ìwọ ti rò sí wa.9Ìbùkún ni fún ẹni tí ó mú ọmọ wẹ́wẹ́ rẹtí ó sì fi wọ́n ṣán òkúta.