Saamu136yor_bib
1Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.2Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run:nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.3Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa,nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.4Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.5Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.6Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.7Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.8Òòrùn láti jẹ ọba ọ̀sán;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.9Òṣùpá àti ìràwọ̀ láti jẹ ọba òru;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.10Fún ẹni tí ó kọlu Ejibiti lára àwọn àkọ́bí wọn;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.11Ó sì mú Israẹli jáde kúrò láàrín wọn;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.12Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.13Fún ẹni tí ó pín Òkun pupa ní ìyà;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.14Ó sì mú Israẹli kọjá láàrín rẹ̀nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.15Ṣùgbọ́n ó bi Farao àti ogun rẹ̀ ṣubú nínú Òkun pupa;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.16Fún ẹni tí ó sin àwọn ènìyàn rẹ̀ la aginjù jánítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.17Fún ẹni tí ó kọlu àwọn ọba ńlá;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.18Ó sì pa àwọn ọba olókìkínítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.19Sihoni, ọba àwọn ará Amorinítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.20Àti Ogu, ọba Baṣani;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.21Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní,nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.22Ìní fún Israẹli, ìránṣẹ́ rẹ̀,nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.23Ẹni tí ó rántí wa ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.24Ó sì dá wa ní ìdè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.25Ẹni tí ó fi oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá gbogbonítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.26Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.