Saamu130yor_bib
Orin fún ìgòkè.
1Láti inú ibú wá nièmi ń ké pè é ọ́ Olúwa2Olúwa, gbóhùn mi,jẹ́ kí etí rẹ kí o tẹ́ sílẹ̀ sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.3Olúwa, ìbá ṣe pé kí ìwọ máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀,Olúwa, tá ni ìbá dúró.4Nítorí ìdáríjì wà lọ́dọ̀ rẹ,kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.5Èmi dúró de Olúwa, ọkàn mi dúró,àti nínú ọ̀rọ̀ rẹ ni èmi ń ṣe ìrètí.6Ọkàn mi dúró de Olúwa,ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ,àní ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ.7Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa:nítorí pé lọ́dọ̀ Olúwa ni àánú wà,àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáǹdè wà.8Òun ó sì dá Israẹli ní ìdèkúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbogbo.