Saamu13yor_bib

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

1Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa? Ìwọ o ha gbàgbé mi títí láé?Yóò tí pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?2Yóò ti pẹ́ tó tí èmi ó máa bá èrò mi jà,àti ní ojoojúmọ́ ni èmi ń ní ìbànújẹ́ ní ọkàn mi?Yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ọ̀tá mi yóò máa borí mi?
3Wò mí kí o sì dá mi lóhùn, Olúwa Ọlọ́run mi.Fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú mi, kí èmi ó má sún oorun ikú.4Ọ̀tá mi wí pé, “Èmi ti ṣẹ́gun rẹ̀,”àwọn ọ̀tá mi yóò yọ̀ tí mo bá ṣubú.
5Ṣùgbọ́n mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà;ọkàn mi ń yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.6Èmi ó máa kọrin sí Olúwa,nítorí ó dára sí mi.