Saamu129yor_bib

Orin fún ìgòkè.

1“Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójúláti ìgbà èwe mi wá,”jẹ́ kí Israẹli kí ó wí nísinsin yìí;2“Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójúláti ìgbà èwe mi wá;síbẹ̀ wọn kò tí ì borí mi.3Àwọn awalẹ̀ walẹ̀ sí ẹ̀yìn mi:wọ́n sì la aporo wọn gígùn.4Olódodo ni Olúwa:ó ti ké okùn àwọn ènìyàn búburú kúrò.”
5Kí gbogbo àwọn tí ó kórìíra Sioni kí ó dààmú,kí wọn kí ó sì yí ẹ̀yìn padà.6Kí wọn kí ó dàbí koríko orí ilẹ̀tí ó gbẹ dànù kí ó tó dàgbàsókè,7èyí tí olóko pípa kó kún ọwọ́ rẹ̀:bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń di ìtí, kó kún apá rẹ̀.8Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń kọjá lọ kò wí pé,ìbùkún Olúwa kí ó pẹ̀lú yín:àwa ń súre fún yin ní orúkọ Olúwa.