Saamu128yor_bib

Orin fún ìgòkè.

1Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa:tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.2Nítorí tí ìwọ yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ rẹìbùkún ni fún ọ; yóò sì dára fún ọ.3Obìnrin rẹ yóò dàbí àjàrà rereeléso púpọ̀ ní àárín ilé rẹ;àwọn ọmọ rẹ yóò dàbí igi olifi tí ó yí tábìlì rẹ ká.4Kíyèsi i pé, bẹ́ẹ̀ ni a ó bùsi i fún ọkùnrin náà,tí ó bẹ̀rù Olúwa.
5Kí Olúwa kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá,kí ìwọ kí ó sì máa rí ìreJerusalẹmu ní ọjọ́ ayé rẹ gbogbo.6Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì máa rí àti ọmọdọ́mọ rẹ.Láti àlàáfíà lára Israẹli.