Saamu125yor_bib
Orin fún ìgòkè.
1Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò dàbí òkè Sioni,tí a kò lè ṣí ní ìdí, bí kò ṣe pé ó dúró láéláé.2Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká,bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yí ènìyàn káláti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.3Nítorí tí ọ̀pá àwọn ènìyàn búburúkì yóò bà lé ìpín àwọn olódodo;kí àwọn olódodo kí ó máa ba àfi ọwọ́ wọn lé ẹ̀ṣẹ̀.4Olúwa ṣe rere fún àwọn ẹni rere,àti fún àwọn tí àyà wọn dúró ṣinṣin.5Bí ó ṣe ti irú àwọn tí wọn yà sí ipa ọ̀nà wíwọ́ wọn;Olúwa yóò jẹ́ kí wọn lọ pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.Ṣùgbọ́n àlàáfíà yóò wà lórí Israẹli.